Orí loníÿe, êdá làyànmö.
Àkúnlêyàn òun ni àdáyébá.
A délé ayé tán ojú þ kán gbogbo wa;
Orí níí ÿatökùn fúnni.
Ìgbà ti ara ènìyàn kò yá,
Òògùn ló lôjö kan ìpönjú,
Orí ló lôjö gbogbo.
Orí çni làwúre çni;
Orí ló yç kénìyàn ó sìn.
Báa bá wálé ayé táa lówó löwö,
Àyànmö ni.
Bí a sì wà lókèèrè, táyé þ yö wa wò níkõrõ,
ßebí orí ló sohun gbogbo.
Ohun ti Táyé þ ÿe tó fi lówó löwö,
Òun ni Këhìndé ÿe tó dolòsì.
Ç má fõrõ àyànmö wéra.
Nítori ohun ti a yàn, õtõõtõ ni,
Báyé bá yçni, ÿebí orí inú çni ni.
Báa bá dènìyàn þlá, ohun táa dì mö kádàrá ni.
Ohun ti a rù lórí, látòde õrun wá ni.
Kò séèyàn ti í paÿô àgùntàn-án dà.
Táyé bá ÿelá tílá fi kó,
Téniyàn ÿekàn tíkàn bá wêwù êjê
Táyé náà bá tún taÿô ìjímèrè bepo
Ká rántí pé ohun táa mú wáyé látòde õrun ni
Kò sëni pa Lágbájá,
Kò sëni pa Làkáÿègbè;
Ó ti wà nínú àkôölê rê ni.
Orí jà ó joògùn
Orí là bá máa bô löjö gbogbo
Orí ni ààbò çni,
Kò sórìÿà ti þ gbeni lëyìn orí çni.
Bénìyàn bá ní wàhálà, orí ni yóò ké sí.
Máà bënìkan sô,
Nítorí ènìyàn kò fêni förõ, à forí çni.
Kókó inú ewì yìí ni pé